Praying in Best Language, Yoruba

YORÙBÁ DÙÚN KÀÁÁÁ      ADURA A B D E E F G GB L'EDE YORUBA.

A - Alaafia ni fun o.

B - Buburu kan ki yo o subu lu o.

D - Dugbedugbe ibanuje ko ni ja le o l'ori.

E - Ebi o ni pa o nibi ti odun yi ku si.

E - Ekun, ose ko ni je tire.

F - Funfun aye re ko ni d'ibaje.


G - Gunnugun ki ku l'ewe, wa d'agba d'arugbo.

GB - Gbogbo idawole re a y'ori si rere.

H - Hausa, Yoruba, Ibo, gbogbo eya ati eniyan kaakiri agbaye ni yo koju si o se o loore.

I - Iwaju, iwaju l'opa ebiti re yo ma re si.

J - Jijade re, wiwole re, o o nik'agbako.

K - Kukuru abi giga, osi ati ise ko ni je tire.

L - Loniloni wa r'aanu gba.

M- Monamona ati ara Olorun yoo tu awon ota re ka.

N - Naira, Euro, Dollar,Pound, Yen, Yuan, gbogbo owo ati oro kaakiri agbaye pelu omo alalubarika ati alaafia yoo mu o l'ore, won o si fi ile re se ibugbe.

O - Ojurere ati aanu yoo ma to o leyin ni ojo aye re gbogbo.

O - Ojo ola re a dara.

P - Panpe aye o ni mu o t'omotomo.

R - Rere ni agogo aye re o ma lu n'igba gbogbo.

S - Suuru pelu itelorun ninu oro at'alaafia yoo ba o kale.

S - Sugbon ati abawon aye re ti poora loni.

T - T'omotomo, t'ebitebi, t'iletile o ni d'ero eyin.

U - "U" ki i s'awati lede Ijesha; a o ni fi o s'awati laarin awon eniyan. Ulosiwaju (ilosiwaju), use (ise) rere, ati ubukun (ibunkun) yio je tire.

W - Wa ri ba ti se, wa r'ona gbe gba.

Y - Yara ibukun, ire, ati ayo ailopin loo ma gbe titi ojo aye re......

AMIN L'ASE EDUMARE. Iwo naa fi ranse si awon ololufe re. Be e si ni o le fi ranse si emi naa ti moba wa lara awon ololufe re .

No comments:

Post a Comment